Numeri 11:30
Numbers 11:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́.
Numbers 11:30 in English
Numbers 11:30 · Berean Standard Bible
Then Moses returned to the camp, along with the elders of Israel.
Context
28Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!” 29Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” 30Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́. 31Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká. 32Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí, ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.