Nehemiah 7:64
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.
Nehemiah 7:64 in English
Nehemiah 7:64 · Berean Standard Bible
These men searched for their family records, but they could not find them and so were excluded from the priesthood as unclean.
Context
62Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642). 63Lára àwọn àlùfáà ni:
àwọn ọmọ
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè). 64Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́. 65Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé. 66Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360),
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.