Nehemiah 7:63
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
Nehemiah 7:63 in English
Nehemiah 7:63 · Berean Standard Bible
And from among the priests: the descendants of Hobaiah, the descendants of Hakkoz, and the descendants of Barzillai (who had married a daughter of Barzillai the Gileadite and was called by their name).
Context
61Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli. 62Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642). 63Lára àwọn àlùfáà ni:
àwọn ọmọ
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè). 64Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́. 65Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.