Nehemiah 6:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli,* láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta.
Nehemiah 6:15 in English
Nehemiah 6:15 · Berean Standard Bible
So the wall was completed in fifty-two days, on the twenty-fifth of Elul.*
Context
13Wọ́n bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rùbà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn. 14A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí. 15Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli,* láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta. 16Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa. 17Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tobiah, èsì láti ọ̀dọ̀ Tobiah sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.