Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.

Nehemiah 6:16 in English

Nehemiah 6:16 · Berean Standard Bible

When all our enemies heard about this, all the surrounding nations were afraid and disheartened, for they realized that this task had been accomplished by our God.

Context

14A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí. 15Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli,* láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta. 16Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa. 17Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tobiah, èsì láti ọ̀dọ̀ Tobiah sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn. 18Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.