Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rùbà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn.

Nehemiah 6:13 in English

Nehemiah 6:13 · Berean Standard Bible

He had been hired to intimidate me so that I would sin by doing as he suggested, so they could give me a bad name in order to discredit me.

Context

11Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sálọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sálọ sínú tẹmpili láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!” 12Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán an, ṣùgbọ́n ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tobiah àti Sanballati ti bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀. 13Wọ́n bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rùbà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn. 14A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí. 15Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli,* láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.