Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí.

Nehemiah 13:12 in English

Nehemiah 13:12 · Berean Standard Bible

and all Judah brought a tenth of the grain, new wine, and oil into the storerooms.

Context

10Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. 11Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. 12Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. 13Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn. 14Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.