Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn.

Nehemiah 13:10 in English

Nehemiah 13:10 · Berean Standard Bible

I also learned that because the portions for the Levites had not been given to them, all the Levites and singers responsible for performing the service had gone back to their own fields.

Context

8Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílé e Tobiah dà síta láti inú iyàrá náà. 9Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí. 10Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. 11Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. 12Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.