Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílé e Tobiah dà síta láti inú iyàrá náà.

Nehemiah 13:8 in English

Nehemiah 13:8 · Berean Standard Bible

And I was greatly displeased and threw all of Tobiah’s household goods out of the room.

Context

6Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀. 7Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run. 8Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílé e Tobiah dà síta láti inú iyàrá náà. 9Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí. 10Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.