Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn aṣọ́nà: Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin.

Nehemiah 11:19 in English

Nehemiah 11:19 · Berean Standard Bible

And the gatekeepers: Akkub, Talmon, and their associates, who kept watch at the gates—172 men.

Context

17Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà; Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀; àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni. 18Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284). 19Àwọn aṣọ́nà: Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin. 20Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀. 21Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.