Nehemiah 11:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn.
Nehemiah 11:21 in English
Nehemiah 11:21 · Berean Standard Bible
The temple servants lived on the hill of Ophel, with Ziha and Gishpa over them.
Context
19Àwọn aṣọ́nà:
Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin. 20Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀. 21Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn. 22Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run. 23Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.