Nehemiah 1:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hanani, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Juda pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jerusalẹmu.
Nehemiah 1:2 in English
Nehemiah 1:2 · Berean Standard Bible
Hanani, one of my brothers, arrived with men from Judah. So I questioned them about the remnant of the Jews who had survived the exile, and also about Jerusalem.
Context
1Ọ̀rọ̀ Nehemiah ọmọ Hakaliah.
Ní oṣù Kisleu ní ogún ọdún (ìjọba Ahaswerusi ọba Persia) nígbà tí mo wà ní ààfin Susa, 2Hanani, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Juda pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jerusalẹmu. 3Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì padà sí agbègbè ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná sun ẹnu ibodè rẹ̀.” 4Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì sọkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.