Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì sọkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run.

Nehemiah 1:4 in English

Nehemiah 1:4 · Berean Standard Bible

When I heard these words, I sat down and wept. I mourned for days, fasting and praying before the God of heaven.

Context

2Hanani, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Juda pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jerusalẹmu. 3Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì padà sí agbègbè ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná sun ẹnu ibodè rẹ̀.” 4Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì sọkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run. 5Nígbà náà ni mo wí pé: “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́. 6Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.