Native Bible

Mark 16:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún.

Mark 16:10 in English

Mark 16:10 · Berean Standard Bible

She went and told those who had been with Him, who were mourning and weeping.

Context

8Wọ́n sáré jáde lọ kánkán, kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n. 9Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde. 10Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún. 11Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́. 12Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.