Native Bible

Mark 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

Mark 16:11 in English

Mark 16:11 · Berean Standard Bible

And when they heard that Jesus was alive and she had seen Him, they did not believe it.

Context

9Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde. 10Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún. 11Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́. 12Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko. 13Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.