Marku 16:12
Mark 16:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko.
Mark 16:12 in English
Mark 16:12 · Berean Standard Bible
After this, Jesus appeared in a different form to two of them as they walked along in the country.
Context
10Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún. 11Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́. 12Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko. 13Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́. 14Lẹ́yìn náà, Jesu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti ń jẹun papọ̀; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.