Native Bible

Mark 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu.

Mark 11:12 in English

Mark 11:12 · Berean Standard Bible

The next day, when they had left Bethany, Jesus was hungry.

Context

10“Olùbùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dafidi, baba wa!” “Hosana lókè ọ̀run!” 11Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá. 12Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. 13Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. 14Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.