Mika 5:10
Micah 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
Micah 5:10 in English
Micah 5:10 · Berean Standard Bible
“In that day,” declares the LORD, “I will remove your horses from among you and wreck your chariots.
Context
8Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà
ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn,
bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó,
bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn,
èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,
tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là. 9A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun. 10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ
èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run. 11Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,
èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya. 12Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,
ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.