Mika 4:8
Micah 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
Micah 4:8 in English
Micah 4:8 · Berean Standard Bible
And you, O watchtower of the flock, O stronghold * of the Daughter of Zion— the former dominion will be restored to you; sovereignty will come to the Daughter of Jerusalem.”
Context
6“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò kó àwọn arọ jọ;
èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ,
àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú. 7Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù,
èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára.
Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 8Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,
odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,
a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;
ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.” 9Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí?
Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí?
Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí?
Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí. 10Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,
ìwọ obìnrin Sioni,
bí ẹni tí ń rọbí,
nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,
ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.
Ìwọ yóò lọ sí Babeli;
níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.