Mika 4:6
Micah 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.
Micah 4:6 in English
Micah 4:6 · Berean Standard Bible
“On that day,” declares the LORD, “I will gather the lame; I will assemble the outcast, even those whom I have afflicted.
Context
4Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀
àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,
ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀. 5Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,
olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,
ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.
Ọlọ́run wa láé àti láéláé. 6“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò kó àwọn arọ jọ;
èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ,
àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú. 7Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù,
èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára.
Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 8Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn,
odi alágbára ọmọbìnrin Sioni,
a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín;
ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.