Native Bible

Micah 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”

Micah 4:11 in English

Micah 4:11 · Berean Standard Bible

But now many nations have assembled against you, saying, “Let her be defiled, and let us feast our eyes on Zion.”

Context

9Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí. 10Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ. 11Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!” 12Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà. 13“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.