Mika 4:12
Micah 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.
Micah 4:12 in English
Micah 4:12 · Berean Standard Bible
But they do not know the thoughts of the LORD or understand His plan, for He has gathered them like sheaves to the threshing floor.
Context
10Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora,
ìwọ obìnrin Sioni,
bí ẹni tí ń rọbí,
nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú,
ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó.
Ìwọ yóò lọ sí Babeli;
níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà.
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ. 11Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ.
Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́,
ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!” 12Ṣùgbọ́n wọn kò mọ
èrò inú Olúwa;
bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn,
nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà. 13“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin,
èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ
ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.”
Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa
àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.