Mika 2:6
Micah 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”
Micah 2:6 in English
Micah 2:6 · Berean Standard Bible
“Do not preach,” they preach. “Do not preach these things; disgrace will not overtake us.”
Context
4Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín;
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé:
‘Ní kíkó a ti kó wọn tán;
Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;
Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ” 5Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa,
tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò. 6“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí.
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;
kí ìtìjú má ṣe le bá wa.” 7Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu:
“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?”
“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere
fún ẹni tí ń rìn déédé bí? 8Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde
bí ọ̀tá sí mi.
Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀
kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,
bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.