Native Bible

Micah 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín; wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”

Micah 2:4 in English

Micah 2:4 · Berean Standard Bible

In that day they will take up a proverb against you and taunt you with this bitter lamentation: ‘We are utterly ruined! He has changed the portion of my people. How He has removed it from me! He has allotted our fields to traitors.’”

Context

2Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀. 3Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi. 4Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín; wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ” 5Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa, tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò. 6“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.