Mika 2:7
Micah 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu: “Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?” “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí?
Micah 2:7 in English
Micah 2:7 · Berean Standard Bible
Should it be said, O house of Jacob, “Is the Spirit of the LORD impatient? Are these the things He does?” Do not My words bring good to him who walks uprightly?
Context
5Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa,
tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò. 6“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí.
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;
kí ìtìjú má ṣe le bá wa.” 7Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu:
“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?”
“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere
fún ẹni tí ń rìn déédé bí? 8Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde
bí ọ̀tá sí mi.
Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀
kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,
bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun. 9Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi
kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,
ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.