Native Bible

Micah 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò.

Micah 2:10 in English

Micah 2:10 · Berean Standard Bible

Arise and depart, for this is not your place of rest, because its defilement brings destruction— a grievous destruction!

Context

8Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi. Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun. 9Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé. 10Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò. 11Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé, ‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’ òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí! 12“Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu; Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.