Mika 2:12
Micah 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu; Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Micah 2:12 in English
Micah 2:12 · Berean Standard Bible
I will surely gather all of you, O Jacob; I will collect the remnant of Israel. I will bring them together like sheep in a pen, like a flock in the midst of its pasture— a noisy throng.
Context
10Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ!
Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín,
nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́
yóò pa yín run,
àní ìparun kíkorò. 11Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé,
‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’
òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí! 12“Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu;
Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ.
Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn,
ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn. 13Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn;
wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ.
Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn,
Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.