Native Bible

Matthew 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ?

Matthew 7:3 in English

Matthew 7:3 · Berean Standard Bible

Why do you look at the speck in your brother’s eye, but fail to notice the beam in your own eye?

Context

1“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín. 3“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.