Matiu 7:2
Matthew 7:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.
Matthew 7:2 in English
Matthew 7:2 · Berean Standard Bible
For with the same judgment you pronounce, you will be judged; and with the measure you use, it will be measured to you.
Context
1“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín. 3“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.