Native Bible

Matthew 26:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

Matthew 26:46 in English

Matthew 26:46 · Berean Standard Bible

Rise, let us go! See, My betrayer is approaching!”

Context

44Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà. 45Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!” 47Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá. 48Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.