Native Bible

Matthew 26:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.

Matthew 26:44 in English

Matthew 26:44 · Berean Standard Bible

So He left them and went away once more and prayed a third time, saying the same thing.

Context

42Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá bí kò ṣe pé mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.” 43Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun. 44Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà. 45Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.