Native Bible

Matthew 23:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni. Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i.

Matthew 23:5 in English

Matthew 23:5 · Berean Standard Bible

All their deeds are done for men to see. They broaden their phylacteries and lengthen their tassels.

Context

3nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. 4Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an. 5“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni. Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. 6Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. 7Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.