Native Bible

Matthew 23:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu.

Matthew 23:6 in English

Matthew 23:6 · Berean Standard Bible

They love the places of honor at banquets, the chief seats in the synagogues,

Context

4Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an. 5“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni. Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. 6Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. 7Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’ 8“Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.