Matiu 21:18
Matthew 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.
Matthew 21:18 in English
Matthew 21:18 · Berean Standard Bible
In the morning, as Jesus was returning to the city, He was hungry.
Context
16Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”
Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé,
“ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú,
ni a ó ti máa yìn mí’?” 17Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Betani. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà. 18Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á. 19Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ láti òní lọ àti títí láé.” Lójúkan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ. 20Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnu yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíá?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.