Matiu 21:16
Matthew 21:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?” Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé, “ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú, ni a ó ti máa yìn mí’?”
Matthew 21:16 in English
Matthew 21:16 · Berean Standard Bible
“Do you hear what these children are saying?” they asked. “Yes,” Jesus answered. “Have you never read: ‘From the mouths of children and infants You have ordained praise’*?”
Context
14A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn. 16Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”
Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé,
“ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú,
ni a ó ti máa yìn mí’?” 17Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Betani. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà. 18Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.