Matiu 21:15
Matthew 21:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn.
Matthew 21:15 in English
Matthew 21:15 · Berean Standard Bible
But the chief priests and scribes were indignant when they saw the wonders He performed and the children shouting in the temple courts, “Hosanna to the Son of David!”
Context
13Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.” 14A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn. 16Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”
Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹ̀yin kò kà á pé,
“ ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú,
ni a ó ti máa yìn mí’?” 17Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Betani. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.