Native Bible

Matthew 21:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”

Matthew 21:13 in English

Matthew 21:13 · Berean Standard Bible

And He declared to them, “It is written: ‘My house will be called a house of prayer.’* But you are making it ‘a den of robbers.’*”

Context

11Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.” 12Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé. 13Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.” 14A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.