Native Bible

Luke 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

Luke 3:6 in English

Luke 3:6 · Berean Standard Bible

And all humanity will see God’s salvation.’”*

Context

4bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́. 5Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ. Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán. 6Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ” 7Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.