Native Bible

Luke 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

Luke 3:7 in English

Luke 3:7 · Berean Standard Bible

Then John said to the crowds coming out to be baptized by him, “You brood of vipers, who warned you to flee from the coming wrath?

Context

5Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ. Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán. 6Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ” 7Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 9Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.