Luku 3:9
Luke 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
Luke 3:9 in English
Luke 3:9 · Berean Standard Bible
The axe lies ready at the root of the trees, and every tree that does not produce good fruit will be cut down and thrown into the fire.”
Context
7Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 9Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.” 10Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” 11Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.