Luku 15:13
Luke 15:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.
Luke 15:13 in English
Luke 15:13 · Berean Standard Bible
After a few days, the younger son got everything together and journeyed to a distant country, where he squandered his wealth in wild living.
Context
11Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì: 12“Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn. 13“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. 14Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. 15Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.