Luku 15:14
Luke 15:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní.
Luke 15:14 in English
Luke 15:14 · Berean Standard Bible
After he had spent all he had, a severe famine swept through that country, and he began to be in need.
Context
12“Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn. 13“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. 14Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. 15Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. 16Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.