Luku 11:6
Luke 11:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’
Luke 11:6 in English
Luke 11:6 · Berean Standard Bible
because a friend of mine has come to me on a journey, and I have nothing to set before him.’
Context
4Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;
nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè,
Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ” 5Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrín ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta. 6Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’ 7Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu, a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’ 8Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.