Native Bible

Luke 11:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́.

Luke 11:8 in English

Luke 11:8 · Berean Standard Bible

I tell you, even though he will not get up to provide for him because of his friendship, yet because of the man’s persistence, he will get up and give him as much as he needs.

Context

6Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’ 7Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu, a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’ 8Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́. 9“Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 10Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.