Lefitiku 13:29
Leviticus 13:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n.
Leviticus 13:29 in English
Leviticus 13:29 · Berean Standard Bible
If a man or woman has an infection on the head or chin,
Context
27Kí àlùfáà yẹ ẹni náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ń ràn ká àwọ̀ ara, kí àlùfáà kí ó pè é ní aláìmọ́. Ààrùn ara tí ń ràn ni èyí. 28Ṣùgbọ́n bí ojú iná náà kò bá yípadà tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara. Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ, ìwú lásán ni èyí láti ojú iná náà; kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Ojú àpá iná lásán ni. 29“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n. 30Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju awọ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ tí kò sì kún; kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́; làpálàpá ni èyí. Ààrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni. 31Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.