Native Bible

Leviticus 13:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

Leviticus 13:31 in English

Leviticus 13:31 · Berean Standard Bible

But if the priest examines the scaly infection and it does not appear to be deeper than the skin, and there is no black hair in it, the priest shall isolate the infected person for seven days.

Context

29“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n. 30Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju awọ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ tí kò sì kún; kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́; làpálàpá ni èyí. Ààrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni. 31Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje. 32Ní ọjọ́ keje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ. 33Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.