Native Bible

Leviticus 13:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.

Leviticus 13:33 in English

Leviticus 13:33 · Berean Standard Bible

then the person must shave himself except for the scaly area. Then the priest shall isolate him for another seven days.

Context

31Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje. 32Ní ọjọ́ keje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ. 33Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. 34Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ keje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara, tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, òun yóò sì mọ́. 35Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fihàn pé ó ti mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.