Native Bible

Leviticus 13:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ keje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara, tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, òun yóò sì mọ́.

Leviticus 13:34 in English

Leviticus 13:34 · Berean Standard Bible

On the seventh day the priest shall examine the scaly outbreak, and if it has not spread on the skin and does not appear to be deeper than the skin, the priest is to pronounce him clean. He must wash his clothes, and he will be clean.

Context

32Ní ọjọ́ keje kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò, bí làpálàpá náà kò bá ràn mọ́ tí kò sì sí irun pípọ́n fẹ́ẹ́rẹ́ nínú rẹ̀ tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ. 33Kí a fá gbogbo irun rẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó dá ojú àpá náà sí, kí àlùfáà sì tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. 34Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ keje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara, tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, òun yóò sì mọ́. 35Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fihàn pé ó ti mọ́. 36Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara; kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́ wò mọ́. Ẹni náà ti di aláìmọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.