Lefitiku 10:1
Leviticus 10:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa.
Leviticus 10:1 in English
Leviticus 10:1 · Berean Standard Bible
Now Aaron’s sons Nadab and Abihu took their censers, put fire in them and added incense, and offered unauthorized * fire before the LORD, contrary to His command.
Context
1Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa. 2Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa. 3Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé,
“ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi,
Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́
ojú gbogbo ènìyàn
Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ”
Aaroni sì dákẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.