Lefitiku 10:3
Leviticus 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé, “ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ” Aaroni sì dákẹ́.
Leviticus 10:3 in English
Leviticus 10:3 · Berean Standard Bible
Then Moses said to Aaron, “This is what the LORD meant when He said: ‘To those who come near Me I will show My holiness, and in the sight of all the people I will reveal My glory.’” But Aaron remained silent.
Context
1Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa. 2Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa. 3Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé,
“ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi,
Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́
ojú gbogbo ènìyàn
Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ”
Aaroni sì dákẹ́. 4Mose pe Miṣaeli àti Elsafani ọmọ Usieli tí í ṣe arákùnrin Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ wá, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín jáde kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ sí ẹ̀yìn ibùdó.” 5Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mose ti sọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.